Ábúsálómù sì ránṣẹ́ pe Áhítófélì ará Gílónì, ìgbìmọ̀ Dáfídì, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Gílónì, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Ábúsálómù.