Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísíráẹ́lì, nítòótọ́, ó sì mú kí ọmọ rẹ̀ ó kọjá láàrin iná, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ ìrírà àwọn aláìkọlà, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísíráẹ́lì.