14. Nísinsìn yìí, ẹ̀mi Olúwa ti kúrò lára Ṣọ́ọ̀lù, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.
15. Àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu.
16. Jẹ́ kí Olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mi búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”
17. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”
18. Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”
19. Ṣọ́ọ̀lù sì rán oníṣẹ́ sí Jésè wí pé, “Rán Dáfídì ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.”
20. Jésè sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ ọ Dáfídì ọmọ rẹ̀ sí Ṣọ́ọ̀lù.