Nísinsìn yìí kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti pàdé mi lórí òkè Kámẹ́lì. Àti kí o sì mú àádọ́tàlénírinwó (450) àwọn wòlíì Báálì àti irinwó (400) àwọn wòlíì ère òrìṣà tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jésébélì.”