Àdóníjà ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Hágátì sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì sètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀.