Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 9:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Si kiyesi i, awọn ọkan ninu awọn akọwe nwi ninu ara wọn pe, ọkunrin yi nsọrọ-odi.

4. Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin?

5. Ewo li o rọrun ju, lati wipe, A dari ẹṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, ki o si mã rìn?

6. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o si wi fun alarun ẹ̀gba na pe,) Dide, si gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.

7. O si dide, o si lọ ile rẹ̀.

8. Nigbati ijọ enia si ri i, ẹnu yà wọn, nwọn yìn Ọlọrun logo, ti o fi irú agbara bayi fun enia.

9. Bi Jesu si ti nrekọja lati ibẹ̀ lọ, o ri ọkunrin kan ti a npè ni Matiu joko ni bode; o sì wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin.

10. O si ṣe, bi Jesu ti joko tì onjẹ ninu ile, si kiyesi i, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá, nwọn si ba a joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

11. Nigbati awọn Farisi si ri i, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Olukọ nyin fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun pọ̀?

12. Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da.

13. Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

14. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Johanu tọ̀ ọ wá wipe, Èṣe ti awa ati awọn Farisi fi ngbàwẹ nigbagbogbo, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?

15. Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ.

16. Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju.

Ka pipe ipin Mat 9