Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 8:28-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Nigbati o si de apa keji ni ilẹ awọn ara Gergesene, awọn ọkunrin meji ẹlẹmi èṣu pade rẹ̀, nwọn nti inu ibojì jade wá, nwọn rorò gidigidi tobẹ̃ ti ẹnikan ko le kọja li ọ̀na ibẹ̀.

29. Si wò o, nwọn kigbe soke wipe, Kini ṣe tawa tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun? iwọ wá lati da wa loro ki o to to akokò?

30. Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ ti njẹ mbẹ li ọ̀na jijìn si wọn.

31. Awọn ẹmi èṣu na si bẹ̀ ẹ, wipe, Bi iwọ ba lé wa jade, jẹ ki awa ki o lọ sinu agbo ẹlẹdẹ yi.

32. O si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ. Nigbati nwọn si jade, nwọn lọ sinu agbo ẹlẹdẹ na; si wò o, gbogbo agbo ẹlẹdẹ na rọ́ sinu okun li ogedengbe, nwọn si ṣegbé ninu omi.

Ka pipe ipin Mat 8