Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 8:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI o ti ori òke sọkalẹ, ọ̀pọ enia ntọ̀ ọ lẹhin.

2. Si wò o, adẹtẹ̀ kan wá, o tẹriba fun u, o wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́.

3. Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o wipe, Mo fẹ; iwọ di mimọ́. Lojukanna ẹ̀tẹ rẹ̀ si mọ́.

4. Jesu si wi fun u pe, Wò o, máṣe sọ fun ẹnikan; ṣugbọn mã ba ọ̀na rẹ lọ, fi ara rẹ hàn fun awọn alufa, ki o si fi ẹ̀bun ti Mose palaṣẹ li ẹrí fun wọn.

5. Nigbati Jesu si wọ̀ Kapernaumu, balogun ọrún kan tọ̀ ọ wá, o mbẹ̀ ẹ,

6. O si nwipe, Oluwa, ọmọ-ọdọ mi dubulẹ arùn ẹ̀gba ni ile, ni irora pupọ̀.

7. Jesu si wi fun u pe, emi mbọ̀ wá mu u larada.

8. Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.

9. Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e.

Ka pipe ipin Mat 8