Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 3:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NI ijọ wọnni ni Johanu Baptisti wá, o nwasu ni ijù Judea,

2. O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.

3. Nitori eyi li ẹniti woli Isaiah sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọ̀na rẹ̀ tọ́.

4. Aṣọ Johanu na si jẹ ti irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ si ẹ̀gbẹ rẹ̀; onjẹ rẹ̀ li ẽṣú ati oyin ìgan.

5. Nigbana li awọn ara Jerusalemu, ati gbogbo Judea, ati gbogbo ẹkùn apa Jordani yiká jade tọ̀ ọ wá,

6. A si mbaptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn.

Ka pipe ipin Mat 3