Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 28:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Bi nwọn si ti nlọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wo o, Jesu pade wọn, o wipe, Alafia. Nwọn si wá, nwọn si gbá a li ẹsẹ mu, nwọn si tẹriba fun u.

10. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹ lọ isọ fun awọn arakunrin mi pe, ki nwọn ki o lọ si Galili, nibẹ̀ ni nwọn o gbé ri mi.

11. Njẹ bi nwọn ti nlọ, wo o, ninu awọn olusọ wá si ilu, nwọn rohin gbogbo nkan wọnyi ti o ṣe fun awọn olori alufa.

12. Nigbati awọn pẹlu awọn agbàgba pejọ, ti nwọn si gbìmọ, nwọn fi ọ̀pọ owo fun awọn ọmọ-ogun na,

13. Nwọn wi fun wọn pe, Ẹ wipe, Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá li oru, nwọn si ji i gbé lọ nigbati awa sùn.

14. Bi eyi ba de etí Bãlẹ, awa o yi i li ọkàn pada, a o si gbà nyin silẹ.

15. Bẹ̃ni nwọn gbà owo na, nwọn si ṣe gẹgẹ bi a ti kọ́ wọn: ọ̀rọ yi si di rirò kiri lọdọ awọn Ju titi di oni.

16. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori òke ti Jesu ti sọ fun wọn.

Ka pipe ipin Mat 28