Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 27:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a:

2. Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ.

3. Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba.

4. O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o.

5. O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso.

6. Awọn olori alufa si mu owo fadaka na, nwọn si wipe, Ko tọ́ ki a fi i sinu iṣura, nitoripe owo ẹ̀jẹ ni.

Ka pipe ipin Mat 27