7. Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ.
8. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo?
9. A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà.
10. Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara.
11. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn ẹnyin kò ni mi nigbagbogbo.
12. Nitori li eyi ti obinrin yi dà ororo ikunra yi si mi lara, o ṣe e fun sisinku mi.
13. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a ba gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ pẹlu li a o si ròhin eyi ti obinrin yi ṣe, ni iranti rẹ̀.
14. Nigbana li ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Judasi Iskariotu tọ̀ awọn olori alufa lọ,
15. O si wipe, Kili ẹnyin o fifun mi, emi o si fi i le nyin lọwọ? Nwọn si ba a ṣe adehùn ọgbọ̀n owo fadaka.
16. Lati igba na lọ li o si ti nwá ọ̀na lati fi i le wọn lọwọ.
17. Nigba ọjọ ikini ajọ aiwukara, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse silẹ dè ọ lati jẹ irekọja?
18. O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi.