Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 26:69-75 Yorùbá Bibeli (YCE)

69. Peteru joko lode li ãfin: nigbana ni ọmọbinrin kan tọ̀ ọ wá, o wipe, Iwọ pẹlu wà pẹlu Jesu ti Galili.

70. Ṣugbọn o sẹ́ li oju gbogbo wọn, o wipe, Emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi.

71. Nigbati o si jade si iloro, ọmọbinrin miran si ri i, o si wi fun awọn ti o wà nibẹ̀ pe, ọkunrin yi wà pẹlu Jesu ti Nasareti.

72. O si tun fi èpe sẹ́, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na.

73. Nigbati o pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun Peteru pe, Lõtọ ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe; nitoripe ohùn rẹ fi ọ hàn.

74. Nigbana li o bẹ̀rẹ si ibura ati si iré, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na. Lojukanna akukọ si kọ.

75. Peteru si ranti ọ̀rọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi lẹrinmẹta. O si bọ si ode, o sọkun kikorò.

Ka pipe ipin Mat 26