66. Ẹnyin ti rò o si? Nwọn dahùn, wipe, O jẹbi ikú.
67. Nigbana ni nwọn tutọ́ si i loju, nwọn kàn a lẹṣẹ́; awọn ẹlomiran fi atẹ́lọwọ́ wọn gbá a loju;
68. Nwọn wipe, Sọtẹlẹ fun wa, iwọ, Kristi, tali ẹniti o nlù ọ ni?
69. Peteru joko lode li ãfin: nigbana ni ọmọbinrin kan tọ̀ ọ wá, o wipe, Iwọ pẹlu wà pẹlu Jesu ti Galili.
70. Ṣugbọn o sẹ́ li oju gbogbo wọn, o wipe, Emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi.
71. Nigbati o si jade si iloro, ọmọbinrin miran si ri i, o si wi fun awọn ti o wà nibẹ̀ pe, ọkunrin yi wà pẹlu Jesu ti Nasareti.
72. O si tun fi èpe sẹ́, wipe, Emi kò mọ̀ ọkunrin na.
73. Nigbati o pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun Peteru pe, Lõtọ ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe; nitoripe ohùn rẹ fi ọ hàn.