Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 26:53-57 Yorùbá Bibeli (YCE)

53. Iwọ ṣebi emi ko le kepè Baba mi, on iba si fun mi jù legioni angẹli mejila lọ lojukanna yi?

54. Ṣugbọn iwe-mimọ́ yio ha ti ṣe ti yio fi ṣẹ, pe bẹ̃ni yio ri?

55. Ni wakati na ni Jesu wi fun ijọ enia pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? li ojojumọ li emi mba nyin joko ni tẹmpili ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si gbé ọwọ́ le mi.

56. Ṣugbọn gbogbo eyi ṣe, ki iwe-mimọ́ awọn wolĩ ba le ṣẹ. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi i silẹ, nwọn si sá lọ.

57. Awọn ti o si mu Jesu, fà a lọ si ile Kaiafa, olori alufa, nibiti awọn akọwe ati awọn agbàgba gbé pejọ si.

Ka pipe ipin Mat 26