Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 26:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a ba gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ pẹlu li a o si ròhin eyi ti obinrin yi ṣe, ni iranti rẹ̀.

14. Nigbana li ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Judasi Iskariotu tọ̀ awọn olori alufa lọ,

15. O si wipe, Kili ẹnyin o fifun mi, emi o si fi i le nyin lọwọ? Nwọn si ba a ṣe adehùn ọgbọ̀n owo fadaka.

16. Lati igba na lọ li o si ti nwá ọ̀na lati fi i le wọn lọwọ.

17. Nigba ọjọ ikini ajọ aiwukara, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse silẹ dè ọ lati jẹ irekọja?

18. O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi.

19. Awọn ọmọ-ẹhin na si ṣe gẹgẹ bi Jesu ti fi aṣẹ fun wọn; nwọn si pèse irekọja silẹ.

20. Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila.

21. Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn.

22. Nwọn si kãnu gidigidi, olukuluku wọn bẹ̀rẹ si ibi i lẽre pe, Oluwa, emi ni bi?

23. O si dahùn wipe, Ẹniti o bá mi tọwọ bọ inu awo, on na ni yio fi mi hàn.

Ka pipe ipin Mat 26