Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 26:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, nigbati Jesu pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe,

2. Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu.

3. Nigbana li awọn olori alufa, awọn akọwe, ati awọn àgba awọn enia pejọ li ãfin olori alufa, ẹniti a npè ni Kaíafa,

4. Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a.

5. Ṣugbọn nwọn wipe, Ki iṣe li ọjọ ajọ, ki ariwo ki o má ba wà ninu awọn enia.

6. Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀,

7. Obinrin kan tọ̀ ọ wá ti on ti ìgò ororo ikunra alabasta iyebiye, o si ndà a si i lori, bi o ti joko tì onjẹ.

8. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, inu wọn ru, nwọn wipe, Nitori kili a ṣe nfi eyi ṣòfo?

9. A ba sá tà ikunra yi ni owo iyebiye, a ba si fifun awọn talakà.

10. Nigbati Jesu mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mba obinrin na wi? nitori iṣẹ rere li o ṣe si mi lara.

Ka pipe ipin Mat 26