Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 22:6-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Awọn iyokù si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn ṣe àbuku si wọn, nwọn si lù wọn pa.

7. Nigbati ọba si gbọ́ eyi, o binu: o si rán awọn ogun rẹ̀ lọ, o pa awọn apania wọnni run, o si kun ilu wọn.

8. Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A se ase iyawo tan, ṣugbọn awọn ti a ti pè kò yẹ.

9. Nitorina ẹ lọ si ọ̀na opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo.

10. Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun.

11. Nigbati ọba na wá iwò awọn ti o wá jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ̀ ti kò wọ̀ aṣọ iyawo:

12. O si bi i pe, Ọrẹ́, iwọ ti ṣe wọ̀ ìhin wá laini aṣọ iyawo? Kò si le fọhùn.

13. Nigbana li ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

14. Nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.

15. Nigbana li awọn Farisi lọ, nwọn gbìmọ bi nwọn o ti ṣe ri ọ̀rọ gbámọ ọ li ẹnu.

16. Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia.

17. Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? o tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́?

18. Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe?

19. Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá.

20. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi?

21. Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.

22. Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ.

23. Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i,

24. Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀.

Ka pipe ipin Mat 22