Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 22:41-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn,

42. Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni.

43. O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe,

44. OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?

45. Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀?

46. Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.

Ka pipe ipin Mat 22