Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 22:28-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i.

29. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun.

30. Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun.

31. Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe,

32. Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye.

33. Nigbati awọn enia gbọ́ eyi, ẹnu yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀.

34. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́ pe, o pa awọn Sadusi li ẹnu mọ́, nwọn pè ara wọn jọ.

35. Nigbana li ọkan ninu wọn, ti iṣe amofin, ndán a wò, o si bi i lẽre ọ̀rọ kan, wipe,

36. Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin?

37. Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ.

38. Eyi li ekini ati ofin nla.

Ka pipe ipin Mat 22