Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 20:28-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.

29. Bi nwọn ti nti Jeriko jade, ọ̀pọ enia tọ̀ ọ lẹhin.

30. Si kiyesi i, awọn ọkunrin afọju meji joko leti ọ̀na, nigbati nwọn gbọ́ pe Jesu nrekọja, nwọn kigbe soke, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.

31. Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.

32. Jesu si dẹsẹ duro, o pè wọn, o si wipe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin?

33. Nwọn wi fun u pe, Oluwa, ki oju wa ki o le là.

34. Bẹ̃ni Jesu ṣãnu fun wọn, o si fi ọwọ́ tọ́ wọn li oju: lọgan oju wọn si là, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.

Ka pipe ipin Mat 20