Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 2:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI a si bí Jesu ni Betlehemu ti Judea, nigba aiye Herodu ọba, kiyesi, awọn amoye kan ti ìha ìla-õrùn wá si Jerusalemu,

2. Nwọn mbère wipe, Nibo li ẹniti a bí ti iṣe ọba awọn Ju wà? nitori awa ti ri irawọ rẹ̀ ni ìla-õrùn, awa si wá lati foribalẹ fun u.

3. Nigbati Herodu ọba si gbọ́, ara rẹ̀ kò lelẹ, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu pẹlu rẹ̀.

4. Nigbati o si pè gbogbo awọn olori alufa ati awọn akọwe awọn enia jọ, o bi wọn lẽre ibiti a o gbé bí Kristi.

5. Nwọn si wi fun u pe, Ni Betlehemu ti Judea ni: nitori bẹ̃li a kọwe rẹ̀ lati ọwọ́ woli nì wá,

6. Iwọ Betlehemu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israeli awọn enia mi.

7. Nigbana ni Herodu pè awọn amoye na si ìkọkọ, o sì bi wọn lẹsọlẹsọ akokò ti irawọ na hàn.

8. O si rán wọn lọ si Betlehemu, o wipe, Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu.

Ka pipe ipin Mat 2