Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 19:24-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.

25. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là?

26. Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe.

27. Nigbana ni Peteru dahùn, o si wi fun u pe, Wò o, awa ti fi gbogbo rẹ̀ silẹ, awa si ntọ̀ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni?

28. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila.

29. Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun.

30. Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

Ka pipe ipin Mat 19