Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 19:12-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a.

13. Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi.

14. Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun.

15. O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀.

16. Si kiyesi i, ẹnikan tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Olukọni rere, ohun rere kili emi o ṣe, ki emi ki o le ni ìye ainipẹkun?

17. O si wi fun u pe, Eṣe ti iwọ fi pè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun: ṣugbọn bi iwọ ba nfẹ wọ̀ ibi ìye, pa ofin mọ́.

18. O bi i lẽre pe, Ewo? Jesu wipe, Iwọ kò gbọdọ pa enia; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jale; Iwọ kò gbọdọ jẹri eke;

19. Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ.

20. Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù?

21. Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin.

22. Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀.

23. Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun.

24. Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.

25. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là?

26. Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe.

27. Nigbana ni Peteru dahùn, o si wi fun u pe, Wò o, awa ti fi gbogbo rẹ̀ silẹ, awa si ntọ̀ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni?

28. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila.

Ka pipe ipin Mat 19