Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 18:25-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Njẹ bi ko ti ni ohun ti yio fi san a, oluwa rẹ̀ paṣẹ pe ki a tà a, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ki a si san gbese na.

26. Nitorina li ọmọ-ọdọ na wolẹ o si tẹriba fun u, o nwipe, Oluwa, mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ.

27. Oluwa ọmọ-ọdọ na si ṣãnu fun u, o tú u silẹ, o fi gbese na jì i.

28. Ṣugbọn nigbati ọmọ-ọdọ na jade lọ, o si ri ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀, ti o jẹ ẹ li ọgọrun owo idẹ: o gbé ọwọ́ le e, o fún u li ọrùn, o wipe, San gbese ti iwọ jẹ mi.

29. Ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀ kunlẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ.

30. On kò si fẹ; o lọ, o gbé e sọ sinu tubu titi yio fi san gbese na.

31. Nigbati awọn iranṣẹ ẹgbẹ rẹ̀ ri eyi ti a ṣe, ãnu ṣe wọn gidigidi, nwọn lọ nwọn si sọ gbogbo ohun ti a ṣe fun oluwa wọn.

32. Nigbati oluwa rẹ̀ pè e tan, o wi fun u pe, A! iwọ iranṣẹ buburu yi, Mo fi gbogbo gbese nì jì ọ, nitoriti iwọ bẹ̀ mi:

33. Iwọ kì isi ṣãnu iranṣẹ ẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi mo ti ṣãnu fun ọ?

34. Oluwa rẹ̀ si binu, o fi i fun awọn onitubu, titi yio fi san gbogbo gbese eyi ti o jẹ ẹ.

35. Bẹ̃ na gẹgẹ ni Baba mi ti mbẹ li ọrun yio si ṣe fun nyin, bi olukuluku kò ba fi tọkàn-tọkan rẹ̀ dari ẹ̀ṣẹ arakunrin rẹ̀ jì i.

Ka pipe ipin Mat 18