Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 17:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin.

18. Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna.

19. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade?

20. Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́ nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe.

21. Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.

22. Nigbati nwọn mbẹ ni Galili, Jesu wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ:

23. Nwọn o si pa a, ni ijọ kẹta yio si jinde. Inu wọn si bajẹ gidigidi.

Ka pipe ipin Mat 17