Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 16:9-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Kò iti yé nyin di isisiyi, ẹnyin kò si ranti iṣu akara marun ti ẹgbẹdọgbọn enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin si kójọ.

10. Ẹ kò si ranti iṣu akara meje ti ẹgbaji enia, ati iye agbọ̀n ti ẹnyin kójọ?

11. Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin pe, emi kò ti itori akara sọ fun nyin pe, ẹ kiyesi ara nyin niti iwukara ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.

12. Nigbana li o to yé wọn pe, ki iṣe iwukara ti akara li o wipe ki nwọn kiyesara rẹ̀, ṣugbọn ẹkọ́ ti awọn Farisi ati ti awọn Sadusi.

13. Nigbati Jesu de igberiko Kesarea Filippi, o bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre, wipe, Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe?

14. Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli.

15. O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè?

16. Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe.

17. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun.

18. Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le; ẹnu-ọ̀na ipo-oku kì yio si le bori rẹ̀.

19. Emi ó si fun ọ ni kọkọrọ ijọba ọrun: ohunkohun ti iwọ ba dè li aiye, a o si dè e li ọrun: ohunkohun ti iwọ ba tú li aiye, a o si tú u li ọrun.

20. Nigbana li o kìlọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o màṣe sọ fun ẹnikan pe, on ni Kristi na.

21. Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde.

22. Nigbana ni Peteru mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi pe, Ki a ma ri i, Oluwa, kì yio ri bẹ̃ fun ọ.

23. Ṣugbọn o yipada, o si wi fun Peteru pe, Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ̀ ni iwọ jẹ fun mi: iwọ ko rò ohun ti iṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi ti iṣe ti enia.

24. Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.

25. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmi rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, yio ri i.

Ka pipe ipin Mat 16