Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 16:22-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Nigbana ni Peteru mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi pe, Ki a ma ri i, Oluwa, kì yio ri bẹ̃ fun ọ.

23. Ṣugbọn o yipada, o si wi fun Peteru pe, Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ̀ ni iwọ jẹ fun mi: iwọ ko rò ohun ti iṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi ti iṣe ti enia.

24. Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.

25. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmi rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, yio ri i.

26. Nitoripe ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ̀ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ̀?

27. Nitori Ọmọ-enia yio wá ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigbana ni yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.

28. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri Ọmọ-enia ti yio ma bọ̀ ni ijọba rẹ̀.

Ka pipe ipin Mat 16