Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 14:22-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Lojukanna Jesu si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o ṣiwaju rẹ̀ lọ si apakeji, nigbati on tú ijọ enia ká.

23. Nigbati o si tú ijọ enia ká tan, o gùn ori òke lọ, on nikan, lati gbadura: nigbati alẹ si lẹ, on nikan wà nibẹ̀.

24. Ṣugbọn nigbana li ọkọ̀ wà larin adagun, ti irumi ntì i siwa sẹhin: nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn.

25. Nigbati o di iṣọ kẹrin oru, Jesu tọ̀ wọn lọ, o nrìn lori okun.

26. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i ti o nrìn lori okun, ẹ̀ru bà wọn, nwọn wipe, Iwin ni; nwọn fi ibẹru kigbe soke.

27. Ṣugbọn lojukanna ni Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tújuka; Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.

28. Peteru si dá a lohùn, wipe, Oluwa, bi iwọ ba ni, paṣẹ ki emi tọ̀ ọ wá lori omi.

29. O si wipe, Wá. Nigbati Peteru sọkalẹ lati inu ọkọ̀ lọ, o rìn loju omi lati tọ̀ Jesu lọ.

30. Ṣugbọn nigbati o ri ti afẹfẹ le, ẹru ba a; o si bẹ̀rẹ si irì, o kigbe soke, wipe, Oluwa, gbà mi.

31. Lojukanna Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o dì i mu, o si wi fun u pe, Iwọ onigbagbọ́ kekere, ẽṣe ti iwọ fi nṣiyemeji?

32. Nigbati nwọn si bọ́ sinu ọkọ̀, afẹfẹ dá.

33. Nigbana li awọn ti mbẹ ninu ọkọ̀ wá, nwọn si fi ori balẹ fun u, wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun ni iwọ iṣe.

34. Nigbati nwọn si rekọja si apakeji, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti.

35. Nigbati awọn enia ibẹ̀ si mọ̀ pe on ni, nwọn ranṣẹ lọ si gbogbo ilu na yiká, nwọn si gbé gbogbo awọn ọlọkunrùn tọ̀ ọ wá.

36. Nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn gbogbo awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, di alara dida ṣáṣá.

Ka pipe ipin Mat 14