Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 13:55-58 Yorùbá Bibeli (YCE)

55. Ọmọ gbẹnagbẹna kọ yi? iya rẹ̀ kọ́ a npè ni Maria? ati awọn arakunrin rẹ̀ kọ́ Jakọbu, Jose, Simoni, ati Juda?

56. Ati awọn arabinrin rẹ̀, gbogbo wọn ki o mba wa gbé nihinyi? nibo li ọkunrin yi ti mu gbogbo nkan wọnyi wa?

57. Bẹ̃ni nwọn kọsẹ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Kò si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu ati ni ile on tikararẹ̀.

58. On kò si ṣe ọ̀pọ iṣẹ agbara nibẹ̀, nitori aigbagbọ́ wọn.

Ka pipe ipin Mat 13