Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 13:45-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

45. Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi ọkunrin oniṣowo kan, ti nwá perli ti o dara:

46. Nigbati o ri perli olowo iyebiye kan, o lọ, o si tà gbogbo nkan ti o ni, o si rà a.

47. Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi àwọn, ti a sọ sinu okun, ti o si kó onirũru ohun gbogbo.

48. Nigbati o kún, eyi ti nwọn fà soke, nwọn joko, nwọn si kó eyi ti o dara sinu agbọ̀n, ṣugbọn nwọn kó buburu danù.

49. Gẹgẹ bẹ̃ni yio si ri nigbẹhin aiye: awọn angẹli yio jade wá, nwọn o yà awọn enia buburu kuro ninu awọn olõtọ,

50. Nwọn o si sọ wọn sinu iná ileru; nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

51. Jesu bi wọn pe, Gbogbo nkan wọnyi yé nyin bi? Nwọn wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa.

52. O si wi fun wọn pe, Nitorina ni olukuluku akọwe ti a kọ́ sipa ijọba ọrun ṣe dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle, ti o nmu ọtun ati ogbó nkan jade ninu iṣura rẹ̀.

53. Nigbati o ṣe, ti Jesu pari owe wọnyi tan, o ti ibẹ̀ lọ kuro.

54. Nigbati o si de ilu on tikalarẹ, o kọ́ wọn ninu sinagogu wọn, tobẹ̃ ti ẹnu yà gbogbo wọn, nwọn si wipe, Nibo li ọkunrin yi ti mu ọgbọ́n yi ati iṣẹ agbara wọnyi wá?

55. Ọmọ gbẹnagbẹna kọ yi? iya rẹ̀ kọ́ a npè ni Maria? ati awọn arakunrin rẹ̀ kọ́ Jakọbu, Jose, Simoni, ati Juda?

56. Ati awọn arabinrin rẹ̀, gbogbo wọn ki o mba wa gbé nihinyi? nibo li ọkunrin yi ti mu gbogbo nkan wọnyi wa?

Ka pipe ipin Mat 13