Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 13:29-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. O si wipe, Bẹ̃kọ, nigbati ẹnyin ba ntu èpo kuro, ki ẹnyin ki o má bà tu alikama pẹlu wọn.

30. Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi.

31. Owe miran li o pa fun wọn, wipe, Ijọba ọrun dabi wóro irugbin mustardi kan, eyiti ọkunrin kan mu ti o si gbìn sinu oko rẹ̀:

32. Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀.

33. Owe miran li o pa fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o sin sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ fi di wiwu.

34. Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu fi powe fun awọn ijọ enia; kò si ba wọn sọ̀rọ bikoṣe li owe:

35. Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá.

36. Nigbana ni Jesu rán ijọ enia lọ, o si wọ̀ ile; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, wipe, Sọ idi owe èpo ti oko fun wa.

37. O dahùn o si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li ẹniti nfunrugbin rere;

38. Oko li aiye; irugbin rere li awọn ọmọ ijọba; èpo si li awọn ọmọ ẹni buburu ni;

39. Ọta ti o fún wọn li Èṣu; igbẹhin aiye ni ikorè; awọn angẹli si li awọn olukore.

40. Nitorina gẹgẹ bi a ti kó èpo jọ, ti a si fi iná sun wọn; bẹ̃ni yio ri ni igbẹhin aiye.

Ka pipe ipin Mat 13