Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 13:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun.

2. Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun.

3. O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin;

4. Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.

5. Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ;

6. Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ.

7. Diẹ si bọ́ sãrin ẹ̀gún; nigbati ẹ̀gún si dàgba soke, o fun wọn pa.

8. Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.

Ka pipe ipin Mat 13