Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 12:14-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.

15. Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada.

16. O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn:

17. Ki eyi ti a ti ẹnu wolĩ Isaiah wi ki o ba le ṣẹ, pe,

18. Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi.

19. On kì yio jà, kì yio si kigbe; bẹ̃li ẹnikẹni kì yio gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro.

20. Iyè fifọ́ ni on kì yio ṣẹ́, owu fitila ti nru ẹ̃fin nì on kì yio si pa, titi yio fi mu idajọ dé iṣẹgun.

21. Orukọ rẹ̀ li awọn keferi yio ma gbẹkẹle.

22. Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran.

23. Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi?

24. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́, nwọn wipe, Ọkunrin yi kò lé awọn ẹmi èṣu jade, bikoṣe nipa Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu.

Ka pipe ipin Mat 12