Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 10:7-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Bi ẹnyin ti nlọ, ẹ mã wasu, wipe, Ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.

8. Ẹ mã ṣe dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, ẹ si jí awọn okú dide, ki ẹ si mã lé awọn ẹmi èṣu jade: ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni.

9. Ẹ máṣe pèse wura, tabi fadaka, tabi idẹ sinu aṣuwọn nyin;

10. Tabi àpo fun àjo nyin, ki ẹ máṣe mu ẹwu meji, tabi bata, tabi ọpá; onjẹ oniṣẹ yẹ fun u.

11. Ilu-kilu tabi iletò-kileto ti ẹnyin ba wọ̀, ẹ wá ẹniti o ba yẹ nibẹ ri, nibẹ̀ ni ki ẹ si gbé titi ẹnyin o fi kuro nibẹ̀.

12. Nigbati ẹnyin ba si wọ̀ ile kan, ẹ kí i.

13. Bi ile na ba si yẹ, ki alafia nyin ki o bà sori rẹ̀; ṣugbọn bi ko ba yẹ, ki alafia nyin ki o pada sọdọ nyin.

14. Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọ́ ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ile na tabi ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin silẹ.

15. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu na lọ.

16. Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba.

17. Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn.

18. A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi.

19. Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna.

20. Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin.

21. Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn.

22. Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà.

Ka pipe ipin Mat 10