Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mat 10:28-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi.

29. Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin.

30. Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan.

31. Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.

32. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.

33. Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.

34. Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà.

35. Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀.

36. Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ̀.

37. Ẹniti o ba fẹ baba tabi iya jù mi lọ, kò yẹ ni temi: ẹniti o ba si fẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù mi lọ, kò si yẹ ni temi.

38. Ẹniti kò ba si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin, kò yẹ ni temi.

39. Ẹniti o ba ri ẹmi rẹ̀, yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on ni yio si ri i.

40. Ẹniti o ba gbà nyin, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi.

41. Ẹniti o ba gbà wolĩ li orukọ wolĩ, yio jẹ ère wolĩ; ẹniti o ba si gbà olododo li orukọ olododo yio jẹ ère olododo.

42. Ẹnikẹni ti o ba fi kìki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, kì o padanù ère rẹ̀.

Ka pipe ipin Mat 10