Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 9:17-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá;

18. Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e.

19. O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi.

20. Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu.

21. O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? o si wipe, Lati kekere ni.

22. Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ.

23. Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́.

24. Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ.

25. Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́.

26. On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú.

27. Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide.

28. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade?

29. O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ.

30. Nwọn si ti ibẹ̀ kuro, nwọn si kọja larin Galili; on kò si fẹ ki ẹnikẹni mọ̀.

31. Nitori o kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ nwọn o si pa a; lẹhin igbati a ba si pa a tan, yio jinde ni ijọ kẹta.

32. Ṣugbọn ọ̀rọ na kò yé wọn, ẹ̀ru si ba wọn lati bi i lẽre.

33. O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na?

Ka pipe ipin Mak 9