Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 7:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN Farisi si pejọ sọdọ rẹ̀, ati awọn kan ninu awọn akọwe ti nwọn ti Jerusalemu wá.

2. Nigbati nwọn ri omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nfi ọwọ aimọ́ jẹun, eyini ni li aiwẹ̀ ọwọ́, nwọn mba wọn wijọ.

3. Nitori awọn Farisi, ati gbogbo awọn Ju, bi nwọn ko ba wẹ̀ ọwọ́ wọn gidigidi, nwọn ki ijẹun, nitoriti nwọn npa ofin atọwọdọwọ awọn àgba mọ́.

4. Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete.

5. Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun?

6. O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.

Ka pipe ipin Mak 7