Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 6:51-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

51. O si wọ̀ inu ọkọ̀ tọ̀ wọn lọ; afẹfẹ si da: ẹ̀ru si ba wọn rekọja gidigidi ninu ara wọn, ẹnu si yà wọn.

52. Nwọn kò sá ronu iṣẹ iyanu ti iṣu akara: nitoriti ọkàn wọn le.

53. Nigbati nwọn si rekọja tan, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti, nwọn si sunmọ eti ilẹ.

54. Bi nwọn si ti njade lati inu ọkọ̀ wá, lojukanna nwọn si mọ̀ ọ,

55. Nwọn si sare lọ si gbogbo igberiko yiká, nwọn bẹ̀rẹ si ima gbé awọn ti ara wọn ṣe alaida wá lori akete, si ibiti nwọn gbọ́ pe o wà.

56. Nibikibi ti o ba si gbé wọ̀, ni iletò gbogbo, tabi ilu nla, tabi arọko, nwọn ngbé olokunrun kalẹ ni igboro, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, a mu wọn larada.

Ka pipe ipin Mak 6