Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 5:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NWỌN si wá si apa keji okun ni ilẹ awọn ara Gadara.

2. Nigbati o si ti inu ọkọ̀ jade, lojukanna ọkunrin kan ti o li ẹmi aimọ pade rẹ̀, o nti ibi ibojì jade wá,

3. Ẹniti o ni ibugbe rẹ̀ ninu ibojì; kò si si ẹniti o le dè e, kò si, kì iṣe ẹ̀wọn:

4. Nitoripe nigbapupọ li a ti nfi ṣẹkẹṣẹkẹ ati ẹ̀wọn de e, on a si dá ẹ̀wọn na meji, a si dá ṣẹkẹṣẹkẹ wẹ́wẹ: bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o li agbara lati se e rọ̀.

5. Ati nigbagbogbo, li ọsán ati li oru, o wà lori òke, ati ninu ibojì, a ma kigbe, a si ma fi okuta pa ara rẹ̀ lara.

6. Ṣugbọn nigbati o ri Jesu li òkere, o sare wá, o si foribalẹ fun u,

7. O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró.

8. Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́.

9. O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀.

10. O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na.

11. Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ kan si wà nibẹ ti njẹ lẹba oke.

12. Gbogbo awọn ẹmi èṣu bẹ̀ ẹ wipe, Rán wa lọ sinu awọn ẹlẹdẹ, ki awa ki o le wọ̀ inu wọn lọ.

13. Lọgan Jesu si jọwọ wọn. Awọn ẹmi aimọ́ si jade, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tupũ nwọn si sure ni gẹrẹgẹrẹ lọ sinu okun (nwọn si to ìwọn ẹgbã;) nwọn si kú sinu okun.

Ka pipe ipin Mak 5