Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 3:20-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ.

21. Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ.

22. Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade.

23. O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade?

24. Bi ijọba kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ijọba na kì yio le duro.

25. Bi ile kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ile na kì yio le duro.

26. Bi Satani ba si dide si ara rẹ̀, ti o si yàpa, on kì yio le duro, ṣugbọn yio ni opin.

27. Kò si ẹniti o le wọ̀ ile ọkunrin alagbara kan lọ, ki o si kó o li ẹrù lọ, bikoṣepe o tètekọ dè ọkunrin alagbara na li okùn; nigbana ni yio le kó o li ẹrù ni ile.

Ka pipe ipin Mak 3