Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 3:15-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade:

16. Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru;

17. Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá:

18. Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,

19. Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.

20. Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ.

21. Nigbati awọn ibatan rẹ̀ si gbọ́ eyini, nwọn jade lọ lati mu u: nitoriti nwọn wipe, Ori rẹ̀ bajẹ.

22. Awọn akọwe ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá, wipe, O ni Beelsebubu, olori awọn ẹmi èṣu li o si fi nlé awọn ẹmi èṣu jade.

23. O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade?

24. Bi ijọba kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ijọba na kì yio le duro.

25. Bi ile kan ba si yàpa si ara rẹ̀, ile na kì yio le duro.

26. Bi Satani ba si dide si ara rẹ̀, ti o si yàpa, on kì yio le duro, ṣugbọn yio ni opin.

27. Kò si ẹniti o le wọ̀ ile ọkunrin alagbara kan lọ, ki o si kó o li ẹrù lọ, bikoṣepe o tètekọ dè ọkunrin alagbara na li okùn; nigbana ni yio le kó o li ẹrù ni ile.

28. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Gbogbo ẹ̀ṣẹ li a o dari wọn jì awọn ọmọ enia, ati gbogbo ọrọ-odi nipa eyiti nwọn o ma fi sọrọ-odi:

29. Ṣugbọn ẹniti o ba sọrọ-odi si Ẹmi Mimọ́ kì yio ni idariji titi lai, ṣugbọn o wà ninu ewu ẹbi ainipẹkun:

30. Nitoriti nwọn wipe, O li ẹmi aimọ́.

31. Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati iya rẹ̀ wá, nwọn duro lode, nwọn si ranṣẹ si i, nwọn npè e.

32. Awọn ọ̀pọ enia si joko lọdọ rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, Wò o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ nwá ọ lode.

33. O si da wọn lohùn, wipe, Tani iṣe iya mi, tabi awọn arakunrin mi?

34. O si wò gbogbo awọn ti o joko lọdọ rẹ̀ yiká, o si wipe, Wò iya mi ati awọn arakunrin mi:

Ka pipe ipin Mak 3