Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 2:3-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé.

4. Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ.

5. Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.

6. Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe,

7. Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun?

8. Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin?

9. Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?

10. Ṣugbọn ki ẹ le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,)

11. Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.

12. O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.

13. O si tún jade lọ si eti okun; gbogbo ijọ enia si wá sọdọ rẹ̀, o si kọ́ wọn.

Ka pipe ipin Mak 2