Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 16:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nigbati Jesu jinde li owurọ̀ kutukutu ni ijọ kini ọ̀sẹ, o kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, lara ẹniti o ti lé ẹmi èṣu meje jade.

10. On si lọ sọ fun awọn ti o ti mba a gbé, bi nwọn ti ngbàwẹ, ti nwọn si nsọkun.

11. Ati awọn, nigbati nwọn si gbọ́ pe o ti di alãye, ati pe, on si ti ri i, nwọn kò gbagbọ.

12. Lẹhin eyini, o si fi ara hàn fun awọn meji ninu wọn li ọna miran, bi nwọn ti nrìn li ọ̀na, ti nwọn si nlọ si igberiko.

13. Nwọn si lọ isọ fun awọn iyokù: nwọn kò si gbà wọn gbọ́ pelu.

14. Lẹhinna o si fi ara hàn fun awọn mọkanla bi nwọn ti joko tì onje, o si ba aigbagbọ́ ati lile àiya wọn wi, nitoriti nwọn ko gbà awọn ti o ti ri i gbọ́ lẹhin igbati o jinde.

15. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.

16. Ẹniti o ba gbagbọ́, ti a ba si baptisi rẹ̀ yio là; ṣugbọn ẹniti kò ba gbagbọ́ yio jẹbi.

17. Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọ̀rọ;

18. Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ́ le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.

19. Bẹ̃ni nigbati Oluwa si ti ba wọn sọ̀rọ tan, a si gbà a lọ soke ọrun, o si joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.

Ka pipe ipin Mak 16