Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 16:15-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.

16. Ẹniti o ba gbagbọ́, ti a ba si baptisi rẹ̀ yio là; ṣugbọn ẹniti kò ba gbagbọ́ yio jẹbi.

17. Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọ̀rọ;

18. Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ́ le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.

19. Bẹ̃ni nigbati Oluwa si ti ba wọn sọ̀rọ tan, a si gbà a lọ soke ọrun, o si joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.

20. Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, Oluwa si mba wọn ṣiṣẹ, o si nfi idi ọ̀rọ na kalẹ, nipa àmi ti ntẹ̀le e. Amin.

Ka pipe ipin Mak 16