53. Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀.
54. Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána.
55. Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan.
56. Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan.
57. Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe,
58. Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe.
59. Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan.
60. Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ?