Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 14:52-65 Yorùbá Bibeli (YCE)

52. O si jọwọ aṣọ ọgbọ na lọwọ, o si sá kuro lọdọ wọn nihoho.

53. Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀.

54. Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána.

55. Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan.

56. Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan.

57. Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe,

58. Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe.

59. Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan.

60. Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ?

61. Ṣugbọn Jesu dakẹ, ko si dahùn ohun kan. Olori alufa si tun bi i lẽre, o wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na, Ọmọ Olubukun nì?

62. Jesu si wipe, Emi ni: ẹnyin o si ri Ọmọ-enia joko li ọwọ́ ọtún agbara, yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá.

63. Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, Ẹlẹri kili a si nwá?

64. Ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na: ẹnyin ti rò o si? Gbogbo wọn si da a lẹbi pe, o jẹbi ikú.

65. Awon miran si bẹ̀rẹ si itutọ́ si i lara, ati si ibò o loju, ati si ikàn a lẹṣẹ́, nwọn si wi fun u pe, Sọtẹlẹ: awọn onṣẹ si nfi atẹlẹ ọwọ́ wọn gbá a loju.

Ka pipe ipin Mak 14