Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 14:41-50 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. O si wá li ẹrinkẹta, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: o to bẹ̃, wakati na de; wo o, a fi Ọmọ-enia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ.

42. Ẹ dide, ki a ma lọ; wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.

43. Lojukanna, bi o si ti nsọ lọwọ, Judasi de, ọkan ninu awọn mejila, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà, pẹlu ọgọ, lati ọdọ olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbagba wá.

44. Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni; ẹ mu u, ki ẹ si ma fà a lọ li alafia.

45. Nigbati o de, o tọ̀ ọ lọ gan, o wipe, Olukọni, olukọni! o si fi ẹnu kò o li ẹnu.

46. Nwọn si gbé ọwọ́ wọn le e, nwọn si mu u.

47. Ṣugbọn ọkan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ fà idà yọ, o si sá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí rẹ̀ kuro.

48. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu?

49. Li ojojumọ li emi wà pẹlu nyin ni tẹmpili, ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si mu mi: ṣugbọn iwe-mimọ kò le ṣe alaiṣẹ.

50. Gbogbo wọn si fi i silẹ, nwọn si sá lọ.

Ka pipe ipin Mak 14