Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 14:17-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nigbati alẹ lẹ, o wá pẹlu awọn mejila.

18. Bi nwọn si ti joko ti nwọn njẹun, Jesu wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọkan ninu nyin yio fi mi hàn, ani on na ti mba mi jẹun.

19. Nwọn si bẹ̀rẹ si ikãnu gidigidi, ati si ibi i lẽre lọkọ̃kan wipe, Emi ni bi? ekeji si wipe, Emi ni bi?

20. O si dahùn o si wi fun wọn pe, Ọkan ninu awọn mejila ni, ti o ntọwọ bọ̀ inu awo pẹlu mi.

21. Nitõtọ Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a kò bí i.

22. Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun wọn, o wipe, Gbà, jẹ: eyiyi li ara mi.

23. O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀.

24. O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia.

25. Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o mu u ni titun ni ijọba Ọlọrun.

26. Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.

27. Jesu si wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru oni: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o lù oluṣọ agutan, a o si tú agbo agutan ká kiri.

28. Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili.

29. Ṣugbọn Peteru wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀, ṣugbọn emi kọ́.

30. Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, loni yi, ani li alẹ yi, ki akukọ ki o to kọ nigba meji, iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta.

31. Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.

32. Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura.

Ka pipe ipin Mak 14