Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 13:17-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmu fun ọmọ mu li ọjọ wọnni!

18. Ki ẹ si ma gbadura, ki sisá nyin ki o máṣe bọ́ si igba otutù.

19. Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si.

20. Bi ko si ṣe bi Oluwa ti ke ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là: ṣugbọn nitoriti awọn ayanfẹ ti o ti yàn, o ti ke ọjọ wọnni kuru.

21. Nitorina bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, wo o, Kristi mbẹ nihinyi; tabi, wo o, o mbẹ lọ́hun; ẹ máṣe gbà a gbọ́:

22. Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã.

23. Ṣugbọn ẹ kiyesara: wo o, mo sọ ohun gbogbo fun nyin tẹlẹ.

24. Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn;

25. Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi.

Ka pipe ipin Mak 13